Oriki Omo Meji.... - TREAT P WORLD

Breaking

Post Top Ad

Responsive Ads Here Contact Treat P

Post Top Ad

Responsive Ads Here Contact Treat P

Tuesday, 25 July 2017

Oriki Omo Meji....

Oriki Ibeji:
Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí,
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣé bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.

Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí  o ló tó ayé wò,
B'ayé dára , bi ko dára

O tó ayé wò,
Ayé dun bi oyin  
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba térin-térin,
Jé kí nrí jé, kí n rí mú.

Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l'ọmọ,
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w'ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo...

Àmín áṣẹ
Ọlánìkẹ́ Apékẹ́ ....

No comments:

Post a Comment

Post Top Ad

Responsive Ads Here Contact Treat P